21. Hadoramu, Usali, ati Dikila;
22. Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba,
23. Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani.
24. Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela;
25. Eberi, Pelegi, Reu;
26. Serugi, Nahori, Tẹra;
27. Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu.
28. Àwọn ọmọ Abrahamu ni Isaaki ati Iṣimaeli.
29. Àkọsílẹ̀ ìran wọn nìyí: Nebaiotu ni àkọ́bí Iṣimaeli, lẹ́yìn náà ni ó bí Kedari, Adibeeli, ati Mibisamu;