17. Ṣemu ni baba Elamu, Aṣuri, ati Apakiṣadi, Ludi, Aramu, ati Usi, Huli, Geteri ati Meṣeki.
18. Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela ni baba Eberi,
19. Eberi bí ọmọkunrin meji: Ekinni ń jẹ́ Pelegi, (nítorí pé ní àkókò tirẹ̀ ni àwọn eniyan ayé pín sí meji); ọmọ Eberi keji sì ń jẹ́ Jokitani,
20. Jokitani ni ó bí Alimodadi, Ṣelefu, Hasarimafeti, ati Jera;
21. Hadoramu, Usali, ati Dikila;
22. Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba,
23. Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani.
24. Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela;
25. Eberi, Pelegi, Reu;
26. Serugi, Nahori, Tẹra;