17. Solomoni lọ sí Esiongeberi ati Elati ní etí òkun ní ilẹ̀ Edomu.
18. Huramu fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi ranṣẹ, wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ofiri pẹlu àwọn iranṣẹ Solomoni, wọ́n sì kó ojilenirinwo ati mẹ́wàá (450) ìwọ̀n talẹnti wúrà wá fún Solomoni ọba.