Kronika Keji 6:39-42 BIBELI MIMỌ (BM)

39. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, jà fún àwọn eniyan rẹ, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ jì wọ́n.

40. “Nisinsinyii, Ọlọrun mi, bojúwò wá kí o sì tẹ́tí sí adura tí wọ́n bá gbà níhìn-ín.

41. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ.

42. Áà! OLUWA Ọlọrun, má ṣe kọ ẹni tí a fi òróró yàn, ranti ìfẹ́ rẹ tí kìí yẹ̀ sí Dafidi, iranṣẹ rẹ.”

Kronika Keji 6