8. Kó igi kedari, sipirẹsi ati aligumu ranṣẹ sí mi láti Lẹbanoni. Mo mọ̀ pé àwọn iranṣẹ rẹ mọ̀ bí wọ́n ṣe ń gé igi ní Lẹbanoni, àwọn iranṣẹ mi náà yóo sì wà pẹlu wọn,
9. láti tọ́jú ọpọlọpọ igi, nítorí pé ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi, yóo sì jọjú.
10. N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.”