Kronika Keji 2:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nítorí náà, fi ọkà baali, òróró ati ọtí tí ìwọ oluwa mi ti ṣèlérí ranṣẹ sí èmi iranṣẹ rẹ.

16. A óo gé gbogbo igi tí o bá nílò ní Lẹbanoni, a óo sì tù wọ́n lójú omi wá sí Jọpa, láti ibẹ̀ ni ẹ lè wá kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.”

17. Solomoni ka gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje, ó lé ẹgbaaje ati ẹgbẹta (153,600).

Kronika Keji 2