Kronika Keji 18:27-30 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára.

28. Ahabu ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda lọ gbógun ti Ramoti Gileadi.

29. Ahabu sọ fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sógun yìí, n óo yí ara pada. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Ọba Israẹli bá yíra pada, ó lọ sí ojú ogun.

30. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀gágun tí wọn ń ṣàkóso àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà bíkòṣe ọba Israẹli nìkan.

Kronika Keji 18