Kronika Keji 16:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.

9. Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.”

10. Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà.

11. Gbogbo nǹkan tí Asa ọba ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli.

12. Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ.

13. Asa kú ní ọdún kọkanlelogoji ìjọba rẹ̀.

14. Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

Kronika Keji 16