Kọrinti Kinni 7:39-40 BIBELI MIMỌ (BM)

39. A ti so obinrin pọ̀ mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti tún ní ọkọ mìíràn tí ó bá fẹ́. Ṣugbọn onigbagbọ nìkan ní ó lè fẹ́.

40. Ṣugbọn mo rò pé ó sàn fún un pupọ jùlọ tí ó bá dá wà. Mo sì rò pé èmi náà ní Ẹ̀mí Ọlọrun.

Kọrinti Kinni 7