Kọrinti Kinni 16:21-24 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí.

22. Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni! Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀!

23. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.

24. Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu.

Kọrinti Kinni 16