Kọrinti Kinni 14:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń tiraka láti ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ máa wá àwọn ẹ̀bùn tí yóo mú ìjọ dàgbà.

13. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ fi níláti gbadura fún ẹ̀bùn láti lè túmọ̀ rẹ̀.

14. Bí mo bá ń fi èdè àjèjì gbadura, ẹ̀mí mi ni ó ń gbadura, ṣugbọn n kò lo òye ti inú ara mi nígbà náà.

Kọrinti Kinni 14