Kọrinti Keji 9:13-15 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nítorí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí àwọn eniyan yóo fi máa yin Ọlọrun fún rírẹ̀ tí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ igbagbọ yín ninu ìyìn rere ti Kristi, ati nítorí ìlawọ́ yín ninu iṣẹ́ yìí fún wọn ati fún gbogbo onigbagbọ.

14. Wọn yóo wá máa gbadura fun yín, ọkàn wọn yóo fà sọ́dọ̀ yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lórí yín.

15. Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà.

Kọrinti Keji 9