1. Ẹẹkẹta nìyí tí n óo wá sọ́dọ̀ yín. Lẹ́nu ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta ni a óo sì ti mọ òtítọ́ gbogbo ọ̀rọ̀.
2. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ fún àwọn tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ ati àwọn yòókù, tí mo tún sọ nígbà tí mo wá sọ́dọ̀ yín lẹẹkeji, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń sọ nisinsinyii tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá tún dé, n kò ní ṣojú àánú;
3. nígbà tí ó ti jẹ́ pé ẹ̀rí ni ẹ̀ ń wá pé Kristi ń lò mí láti sọ̀rọ̀. Kristi kì í ṣe aláìlera ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu yín.
4. Òtítọ́ ni pé a kàn án mọ́ agbelebu ní àìlera, ṣugbọn ó wà láàyè nípa agbára Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé àwa náà jẹ́ aláìlera pẹlu rẹ̀, ṣugbọn a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀ nípa agbára Ọlọrun ninu ìbálò wa pẹlu yín.
5. Ẹ yẹ ara yín wò bí ẹ bá ń gbé ìgbé-ayé ti igbagbọ. Ẹ yẹ ara yín wò. Àbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ̀ pé Kristi Jesu wà ninu yín? Àfi bí ẹ bá ti kùnà nígbà tí ẹ yẹ ara yín wò!