Kọrinti Keji 12:19-21 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣé ohun tí ẹ ti ń rò ni pé à ń wí àwíjàre níwájú yín? Rárá o! Níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ni à ń sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gbogbo nǹkan tí à ń ṣe, fún ìdàgbàsókè yín ni.

20. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò.

21. Ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà tí mo bá tún dé, kí Ọlọrun mi má dójú tì mí níwájú yín, kí n má ní ìbànújẹ́ nítorí ọpọlọpọ tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọn kò ronupiwada kúrò ninu ìṣekúṣe, àgbèrè ati ìwà wọ̀bìà tí wọ́n ti ń hù.

Kọrinti Keji 12