11. Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki.
12. Àwọn àmì aposteli hàn ninu iṣẹ́ mi láàrin yín nípa oríṣìíríṣìí ìfaradà, nípa iṣẹ́ abàmì, iṣẹ́ ìyanu, ati iṣẹ́ agbára.
13. Ọ̀nà wo ni a fi ba yín lò tí ó burú ju ti àwọn ìjọ ìyókù lọ; àfi ti pé èmi fúnra mi kò ni yín lára? Ẹ forí jì mí fún àṣìṣe yìí!
14. Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ.
15. Ní tèmi, pẹlu ayọ̀ ni ǹ bá fi náwó-nára patapata fún ire ọkàn yín. Bí èmi bá fẹ́ràn yín pupọ, ṣé díẹ̀ ni ó yẹ kí ẹ̀yin fẹ́ràn mi?
16. Ẹ gbà pé n kò ni yín lára. Ṣugbọn àwọn kan rò pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni mí, ati pé ẹ̀tàn ni mo fi mu yín.