1. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́, kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ kí o lọ sí ìlú Ai. Wò ó! Mo ti fi ọba Ai, ati àwọn eniyan rẹ̀, ìlú rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.
2. Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”
3. Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́.
4. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀.
5. Èmi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu mi nìkan ni a óo wọ ìlú náà. Nígbà tí wọ́n bá jáde sí wa láti bá wa jà bí i ti àkọ́kọ́, a óo sá fún wọn.
6. Wọn yóo máa lé wa lọ títí tí a óo fi tàn wọ́n jáde kúrò ninu ìlú, nítorí wọn yóo ṣe bí à ń sálọ fún wọn bíi ti àkọ́kọ́ ni; nítorí náà ni a óo ṣe sá fún wọn.