14. “Nisinsinyii, ó tó àkókò fún mi láti kú, gbogbo yín ni ẹ sì mọ̀ dájúdájú ninu ọkàn yín pé, ninu gbogbo àwọn ohun rere tí OLUWA Ọlọrun yín ṣèlérí fun yín, kò sí èyí tí kò mú ṣẹ. Gbogbo wọn patapata ni wọ́n ṣẹ, ẹyọ kan kò yẹ̀ ninu wọn.
15. Ṣugbọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa àwọn nǹkan dáradára tí ó pinnu láti ṣe fun yín, bákan náà ni yóo mú kí gbogbo àwọn nǹkan burúkú tí ó ti ṣèlérí wá sórí yín, títí tí yóo fi run yín patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín,
16. tí ẹ kò bá pa majẹmu tí ó pa láṣẹ fun yín mọ́. Tí ẹ bá lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì foríbalẹ̀ fún wọn, inú yóo bí OLUWA si yín, ẹ óo sì parun kíákíá lórí ilẹ̀ dáradára tí ó ti fun yín.”