36. Adama, Rama, Hasori;
37. Kedeṣi, Edirei, Enhasoru,
38. Yironi, Migidalieli, Horemu, Betanati ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo ìlú ati àwọn ìletò wọn jẹ́ mọkandinlogun.
39. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Nafutali gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
40. Ilẹ̀ keje tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Dani.
41. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Sora, Ẹṣitaolu, Iriṣemeṣi;
42. Ṣaalibimu, Aijaloni, Itila,
43. Eloni, Timna, Ekironi,
44. Eliteke, Gibetoni, Baalati;
45. Jehudi, Beneberaki, Gati Rimoni
46. ati Mejakoni, ati Rakoni pẹlu agbègbè tí ó dojú kọ Jọpa.
47. Nígbà tí ilẹ̀ ẹ̀yà Dani bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n bá lọ gbógun ti ìlú Leṣemu, wọ́n ṣẹgun wọn, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. Wọ́n yí orúkọ Leṣemu pada sí Dani, tíí ṣe orúkọ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
48. Àwọn ìlú ati àwọn ìletò wọnyi ni ìpín tí ó kan ẹ̀yà Dani gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.