Joṣua 15:53-63 BIBELI MIMỌ (BM)

53. Beti Tapua, Afeka, Humita,

54. Kiriati Ariba (tí à ń pè ní Heburoni), ati Siori, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹsan-an.

55. Maoni, Kamẹli, Sifi, Juta.

56. Jesireeli, Jokideamu, Sanoa,

57. Kaini, Gibea, ati Timna, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹ́wàá.

58. Halihuli, Betisuri, Gedori,

59. Maarati, Betanotu, ati Elitekoni, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹfa.

60. Kiriati Baali (tí wọn ń pè ní Kiriati Jearimu), ati Raba, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ meji.

61. Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní aṣálẹ̀ ni, Betaraba, Midini, Sekaka;

62. Nibiṣani, Ìlú Iyọ̀, ati Engedi; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹfa.

63. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda kò lè lé àwọn Jebusi tí wọn ń gbé inú ilẹ̀ Jerusalẹmu jáde. Àwọn Jebusi yìí sì tún wà láàrin àwọn eniyan Juda ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí.

Joṣua 15