43. Aṣinai, Nesibu, Keila;
44. Akisibu, ati Mareṣa; gbogbo ìlú ati ìletò wọ́n jẹ́ mẹsan-an.
45. Ekironi pẹlu àwọn ìlú ati ìletò rẹ̀;
46. láti Ekironi títí dé etí òkun Mẹditarenia, ati gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n wà lẹ́bàá Aṣidodu pẹlu àwọn ìletò wọn.
47. Aṣidodu, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò rẹ̀; Gasa, pẹlu àwọn ìlú ati àwọn ìletò rẹ̀ títí dé odò Ijipti, ati etí òkun Mẹditarenia, pẹlu agbègbè rẹ̀.
48. Àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè nìwọ̀nyí: Ṣamiri,
49. Jatiri, Soko, Dana, Kiriati Seferi (tí à ń pè ní Debiri),
50. Anabu, Eṣitemoa, Animi,
51. Goṣeni, Holoni, ati Gilo; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mọkanla.
52. Arabu, Duma, Eṣani, Janimu,
53. Beti Tapua, Afeka, Humita,
54. Kiriati Ariba (tí à ń pè ní Heburoni), ati Siori, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹsan-an.
55. Maoni, Kamẹli, Sifi, Juta.
56. Jesireeli, Jokideamu, Sanoa,
57. Kaini, Gibea, ati Timna, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹ́wàá.