Joṣua 15:19-35 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀.

20. Èyí ni ilẹ̀ ẹ̀yà Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

21. àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní ìpẹ̀kun apá ìhà gúsù lẹ́bàá ààlà Edomu nìwọ̀nyí: Kabiseeli, Ederi, Jaguri,

22. Kina, Dimona, Adada,

23. Kedeṣi, Hasori, Itinani;

24. Sifi, Telemu, Bealoti;

25. Hasori Hadata, Kerioti Hesironi (tí a tún ń pè ní Hasori);

26. Amamu, Ṣema, Molada;

27. Hasari Gada, Heṣimoni, Betipeleti;

28. Hasari Ṣuali, Beeriṣeba, Bisiotaya;

29. Baala, Iimu, Esemu;

30. Elitoladi, Kesili, Horima;

31. Sikilagi, Madimana, Sansana;

32. Lebaotu, Ṣilihimu, Aini ati Rimoni; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mọkandinlọgbọn.

33. Àwọn ìlú wọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè nìwọ̀nyí: Eṣitaolu, Sora, Aṣinai.

34. Sanoa, Enganimu, Tapua, Enamu;

35. Jarimutu, Adulamu, Soko, Aseka;

Joṣua 15