14. Àwọn ọmọ Israẹli kó gbogbo dúkìá ìlú náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní ìkógun, ṣugbọn wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ run patapata, wọn kò dá ẹyọ ẹnìkan sí.
15. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, iranṣẹ rẹ̀, ni Mose náà ṣe pàṣẹ fún Joṣua, tí Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ohunkohun sílẹ̀ láìṣe, ninu gbogbo nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.
16. Gbogbo ilẹ̀ náà ni Joṣua gbà: ó gba àwọn agbègbè olókè, àwọn tí wọ́n wà ní Nẹgẹbu, gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ Goṣeni, àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àwọn tí ó wà ní Araba, ati gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí àwọn òkè Israẹli ati ẹsẹ̀ òkè rẹ̀.
17. Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.
18. Joṣua bá àwọn ọba wọnyi jagun fún ìgbà pípẹ́.
19. Kò sí ìlú tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia àfi àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé ìlú Gibeoni. Gbogbo àwọn yòókù patapata ni wọ́n kó lójú ogun.
20. Nítorí pé, OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n sì gbógun ti Israẹli, kí àwọn ọmọ Israẹli lè pa wọ́n run, kí wọ́n má baà ṣàánú wọn, ṣugbọn kí wọ́n pa wọ́n run gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
21. Ní àkókò yìí ni Joṣua pa ìran àwọn Anakimu run patapata ní gbogbo àwọn ìlú tí ó wà lórí òkè, àwọn ìlú bíi: Heburoni, Debiri, Anabu, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Juda, ati àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè Israẹli, gbogbo wọn patapata ni Joṣua parun, ati gbogbo ìlú wọn.
22. Àwọn ìran Anakimu yìí kò kù sí ibikíbi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, àfi ní ìlú Gasa, ìlú Gati, ati ìlú Aṣidodu ni àwọn díẹ̀ kù sí.