23. Ṣugbọn àwọn ọkọ̀ mìíràn wá láti Tiberiasi lẹ́bàá ibi tí àwọn eniyan ti jẹun lẹ́yìn tí Oluwa ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun.
24. Nígbà tí àwọn eniyan rí i pé Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn náà bọ́ sinu àwọn ọkọ̀ tí ó wà níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tọpa Jesu lọ sí Kapanaumu.
25. Nígbà tí wọ́n rí i ní òdìkejì òkun, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, nígbà wo ni o ti dé ìhín?”
26. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí iṣẹ́ ìyanu mi ni ẹ ṣe ń wá mi, ṣugbọn nítorí ẹ jẹ oúnjẹ àjẹyó ni.
27. Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.”
28. Wọ́n wá bi í pé, “Kí ni kí á ṣe kí á lè máa ṣe iṣẹ́ Ọlọrun?”