1. Lẹ́yìn èyí, ó tó àkókò fún ọ̀kan ninu àjọ̀dún àwọn Juu: Jesu bá lọ sí Jerusalẹmu.
2. Ẹnu ọ̀nà kan wà ní Jerusalẹmu tí wọn ń pè ní ẹnu ọ̀nà Aguntan. Adágún omi kan wà níbẹ̀ tí ń jẹ́ Betisata ní èdè Heberu. Adágún yìí ní ìloro marun-un tí wọn fi òrùlé bò.
3. Níbẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn aláìsàn ti máa ń jókòó: àwọn afọ́jú, àwọn arọ, ati àwọn tí ó ní àrùn ẹ̀gbà. Wọn a máa retí ìgbà tí omi yóo rú pọ̀; [
4. nítorí angẹli Oluwa a máa wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti rú omi adágún náà pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ bọ́ sinu adágún náà lẹ́yìn tí omi náà bá ti rú pọ̀, àìsànkáìsàn tí ó lè máa ṣe é tẹ́lẹ̀, yóo san.]
5. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ó ti ń ṣàìsàn fún ọdún mejidinlogoji.
6. Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”
7. Aláìsàn náà dáhùn pé, “Alàgbà, n kò ní ẹni tí yóo gbé mi sinu adágún nígbà tí omi bá rú pọ̀, nígbà tí n óo bá fi dé ibẹ̀, ẹlòmíràn á ti wọ inú omi ṣiwaju mi.”
8. Jesu wí fún un pé, “Dìde, ká ẹní rẹ, kí o máa rìn.”