24. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.”
25. Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.”
26. Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.”
27. Ní àkókò yìí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé. Ẹnu yà wọ́n pé obinrin ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni ninu wọn kò bi obinrin náà pé kí ni ó ń wá? Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò bi òun náà pé kí ló dé tí ó fi ń bá obinrin sọ̀rọ̀?
28. Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé,
29. “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?”
30. Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.
31. Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”