Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.