12. Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè.
13. Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun.
14. Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa.
15. Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà.