Johanu Kinni 3:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Gbogbo ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ ń rú òfin, nítorí rírú òfin ni ẹ̀ṣẹ̀.

5. Ẹ sì mọ̀ pé Jesu wá láti kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun alára kò dá ẹyọ ẹ̀ṣẹ̀ kan.

6. Gbogbo ẹni tí ó bá ń gbé inú rẹ̀ kò ní máa dẹ́ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ kò ì tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n.

7. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe òdodo ni olódodo, bí Jesu ti jẹ́ olódodo.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Èṣù ni ó ti wá, nítorí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọrun ṣe wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run.

9. Gbogbo ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí irú-ọmọ Ọlọrun yóo máa gbé inú olúwarẹ̀, nítorí náà, kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

Johanu Kinni 3