5. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí,gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò.
6. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ,Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí.
7. “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́,ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́.
8. Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́;níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́.
9. Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí,kò ní pada mọ́.
10. Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́.
11. “Nítorí náà, n kò ní dákẹ́;n óo sọ ìrora ọkàn mi;n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde.
12. Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi,tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí?