Jobu 5:5-20 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gúnni ó ti mú un jáde,àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri.

6. Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde.

7. A bí eniyan sinu wahalabí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.

8. “Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA,n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́;

9. ẹni tíí ṣe ohun ńlátí eniyan kò lè rídìí,ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà.

10. A máa rọ òjò sórí ilẹ̀,a sì máa bomi rin oko.

11. A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga,a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́.

12. A máa da ète àwọn alárèékérekè rú,kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.

13. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.

14. Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan,wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.

15. Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn,ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16. Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka,a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

17. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí,nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.

18. Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́,ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni.Ó ń pa ni lára,ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.

19. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà,bí ibi ń ṣubú lu ara wọn,kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.

20. Ní àkókò ìyàn,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú.Ní àkókò ogun,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

Jobu 5