24. O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu.Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ,kò ní dín kan.
25. Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀,bí ewéko ninu pápá oko.
26. O óo di arúgbó kí o tó kú,gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbókí á tó kó o wá síbi ìpakà.
27. Wò ó! A ti wádìí àwọn nǹkan wọnyi,òtítọ́ ni wọ́n.Gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”