Jobu 5:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀,owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan.

3. Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀,ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú.

4. Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀,wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè,kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là.

5. Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gúnni ó ti mú un jáde,àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri.

6. Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde.

7. A bí eniyan sinu wahalabí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.

Jobu 5