Jobu 5:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan,wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.

15. Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn,ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16. Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka,a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

17. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí,nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.

18. Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́,ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni.Ó ń pa ni lára,ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.

19. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà,bí ibi ń ṣubú lu ara wọn,kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.

20. Ní àkókò ìyàn,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú.Ní àkókò ogun,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

Jobu 5