Jobu 41:10-20 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?Ta ló tó kò ó lójú?

11. Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.

12. “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.

13. Ta ló tó bó awọ rẹ̀,tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?

14. Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀?Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù.

15. Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata,a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì.

16. Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́,tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn.

17. Wọ́n so pọ̀,wọ́n lẹ̀ mọ́ ara wọn tóbẹ́ẹ̀,tí ohunkohun kò lè ṣí wọn.

18. Bí ó bá sín, ìmọ́lẹ̀ á tàn jáde ní imú rẹ̀,ojú rẹ̀ ń tàn bíi ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ kutukutu.

19. Ahọ́n iná ń yọ lẹ́nu rẹ̀ bí iná tí ń ta jáde,bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n iná ń yọ lálá.

20. Èéfín ń jáde ní imú rẹ̀,bíi ti ìkòkò gbígbóná ati ìgbẹ́ tí ń jó.

Jobu 41