6. Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,
7. “Múra gírí bí ọkunrin,mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.
8. Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni?O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?
9. Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun,àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?
10. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́,kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ.
11. Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga,kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.