Jobu 38:15-26 BIBELI MIMỌ (BM)

15. A mú ìmọ́lẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni ibi,a sì ká wọn lápá kò.

16. “Ṣé o ti wọ orísun òkun lọ rí,tabi o ti rìn nísàlẹ̀ ibú rí?

17. Ṣé a ti fi ìlẹ̀kùn ikú hàn ọ́ rí,tabi o ti rí ìlẹ̀kùn òkùnkùn biribiri rí?

18. Ṣé o mọ̀ bí ayé ti tóbi tó?Dá mi lóhùn, bí o bá mọ àwọn nǹkan wọnyi.

19. “Níbo ni ọ̀nà ilé ìmọ́lẹ̀,ibo sì ni ibùgbé òkùnkùn,

20. tí o óo fi lè mú un lọ sí ààyè rẹ̀,tí o fi lè mọ ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀?

21. Dájúdájú o mọ̀, nítorí pé wọ́n ti bí ọ nígbà náà,o sá ti dàgbà!

22. “Ṣé o ti wọ àwọn ilé ìkẹ́rùsí, tí mò ń kó yìnyín pamọ́ sí rí,tabi ibi tí mò ń kó òjò dídì sí,

23. àní, àwọn tí mo ti pamọ́ de àkókò ìyọnu,fún ọjọ́ ogun ati ọjọ́ ìjà?

24. Ṣé o mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ ti ń tàn wá,tabi ibi tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sórí ayé?

25. “Ta ló lànà fún ọ̀wààrà òjò,ati fún ààrá,

26. láti rọ òjò sí orí ilẹ̀ níbi tí kò sí eniyan,ati ní aṣálẹ̀, níbi tí kò sí ẹnikẹ́ni?

Jobu 38