1. Nígbà náà ni OLUWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì líle.
2. Ó bi í pé,“Ta ni ẹni tí ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ràn,tí ń sọ̀rọ̀ tí kò ní ìmọ̀?
3. Nisinsinyii, múra gírí bí ọkunrin,mo ní ìbéèrè kan láti bí ọ, o óo sì dá mi lóhùn.
4. Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi.