Jobu 37:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀,òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.

10. Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá,gbogbo omi inú odò sì dì.

11. Ó fi omi kún inú ìkùukùu,ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.

12. Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀,láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.

13. Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀,bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀,tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.

14. “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.

15. Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?

16. Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;

17. ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?

Jobu 37