Jobu 37:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. “Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu,dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.

15. Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ,tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?

16. Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀,iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;

17. ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?

18. Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ,kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?

19. Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ,a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀,nítorí àìmọ̀kan wa.

20. Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni?Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì?

21. “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀runnígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma,nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.

22. Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ,ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.

Jobu 37