Jobu 3:19-26 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀,àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn.

20. “Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀fún ẹni tí ń kérora,tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́;

21. tí ó ń wá ikú,ṣugbọn tí kò rí;tí ó ń wá ikú lójú mejeejiju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ?

22. Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọbí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin.

23. Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú;ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́?

24. Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi,ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi.

25. Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi,ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.

26. N kò ní alaafia,bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí,n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.”

Jobu 3