13. Ǹ bá ti dùbúlẹ̀,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́;ǹ bá ti sùn,ǹ bá sì ti máa sinmi
14. pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn,àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn;
15. tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà,tí fadaka sì kún ilé wọn.
16. Tabi kí n rí bí ọmọtí a bí ní ọjọ́ àìpé,tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé.
17. Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́,tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi.
18. Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn,wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́.
19. Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀,àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn.