12. Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti fojú yín rí i,kí ló wá dé tí gbogbo yín fí ń sọ ìsọkúsọ?”
13. “Ìpín ẹni ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìyí,òun ni ogún tí àwọn aninilára ń rí gbà lọ́dọ̀ Olodumare:
14. Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń pọ̀ sí i,kí ogun baà lè pa wọ́n ni,oúnjẹ kò sì ní ká wọn lẹ́nu.
15. Àwọn ọmọ tí wọn bá gbẹ̀yìn rẹ̀,àjàkálẹ̀ àrùn ni yóo pa wọ́n,àwọn opó wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ wọn.