Jobu 23:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀?Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

7. Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀,yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae.

8. “Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀,mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀.

9. Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i,mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀.

10. Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi,ìgbà tí ó bá dán mi wò tán,n óo yege bíi wúrà.

11. Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.

12. N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde,mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi.

13. “Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada,kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada.Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe.

Jobu 23