Jobu 23:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀,tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí.

16. Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,Olodumare ti dẹ́rùbà mí.

17. Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká,òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú.

Jobu 23