Jobu 23:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé,

2. “Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn,ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora.

3. Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni,ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀!

4. Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé.

5. Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi,ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi.

6. Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀?Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

Jobu 23