Jobu 22:15-30 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé;ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn?

16. A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó,a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ.

17. Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé,‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’

18. Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn–ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi.

19. Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn,àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà,

20. wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun,iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’

21. “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun,kí o sì wà ní alaafia;kí ó lè dára fún ọ.

22. Gba ìtọ́ni rẹ̀,kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn.

23. Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀,tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ,

24. bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀,tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò,

25. bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ,ati fadaka olówó iyebíye rẹ,

26. nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare,o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun.

27. Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́,o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.

28. Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe,yóo ṣeéṣe fún ọ,ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ.

29. Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀,a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀.

30. A máa gba àwọn aláìṣẹ̀,yóo sì gbà ọ́ là,nípa ìwà mímọ́ rẹ.”

Jobu 22