9. Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.
10. Àwọn mààlúù wọn ń gùn,wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.
11. Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.
12. Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.
13. Wọn a máa gbé inú ọlá,wọn a sì máa kú ikú alaafia.
14. Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀!A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.