Jobu 21:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín,kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu.

6. Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi,ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì.

7. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè,tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára?

8. Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọndi eniyan pataki pataki lójú ayé wọn.

9. Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.

10. Àwọn mààlúù wọn ń gùn,wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.

11. Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran,àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.

12. Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin,wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.

13. Wọn a máa gbé inú ọlá,wọn a sì máa kú ikú alaafia.

14. Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀!A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.

Jobu 21