Jobu 20:7-23 BIBELI MIMỌ (BM)

7. yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀,àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’

8. Yóo parẹ́ bí àlá,yóo sì di àwátì,yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru.

9. Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́,ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo.

10. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní,wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada.

11. Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára,sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀.

12. Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀,tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀,

13. bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde,tí ó pa ẹnu mọ́,

14. sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú,ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.

15. Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde;Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀.

16. Yóo mu oró ejò,ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á.

17. Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò.

18. Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀.

19. Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀,ó sì ti pa wọ́n tì sí apákanó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́.

20. Nítorí pé oníwọ̀ra ni,tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan,kò lè pa á mọ́ra.

21. Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù,nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.

22. Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.

23. Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,tí yóo sì dà lé e lórí.

Jobu 20