18. Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀.
19. Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀,ó sì ti pa wọ́n tì sí apákanó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́.
20. Nítorí pé oníwọ̀ra ni,tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan,kò lè pa á mọ́ra.
21. Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù,nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.
22. Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́,ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.
23. Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó,ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i,tí yóo sì dà lé e lórí.
24. Bí ó bá ti ń sá fún idà,bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.
25. Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀,tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.
26. Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é,iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun,ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.
27. Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn,ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́.
28. Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ,àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù.
29. Bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ibi yóo rí.Ọlọrun ni ó ti yàn án bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ wá.”